Isaiah10yor_bib
1Ègbé ni fún àwọn ti ń ṣe òfin àìṣòdodo,2láti dún àwọn aláìní ní ẹ̀tọ́ wọnàti láti fa ọwọ́ ìdájọ́ sẹ́yìn kúrò níwájú àwọn olùpọ́njú ènìyàn mi,wọ́n sọ àwọn ọ̀pọ̀ di ìjẹ fún wọn,wọ́n sì ń ja àwọn aláìní baba lólè.3Kí ni ìwọ yóò ṣe ní ọjọ́ ìṣirònígbà tí ìparun bá ti ọ̀nà jíjìn wá?Ta ni ìwọ yóò sá tọ̀ fún ìrànlọ́wọ́?Níbo ni ìwọ yóò fi ọrọ̀ rẹ sí?4Ohunkóhun kò ní ṣẹ́kù mọ́ bí kò ṣe láti tẹ̀ ba láàrín àwọn ìgbèkùntàbí kí o ṣubú sáàrín àwọn tí a pa.Pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ìbínú rẹ̀ kò kúrò,ọwọ́ rẹ̀ sì tún gbé sókè.