Hosea6yor_bib

Àìronúpìwàdà Israẹli

1“Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a padà sọ́dọ̀ Olúwaó ti fà wá ya pẹ́rẹpẹ̀rẹṣùgbọ́n yóò mú wa láradáÓ ti pa wá láraṣùgbọ́n yóò dí ojú ọgbẹ́ wa.2Lẹ́yìn ọjọ́ méjì, yóò sọ wá jíní ọjọ́ kẹta yóò mú wa padà bọ̀ sípòkí a ba à le wá gbé níwájú rẹ̀.3Ẹ jẹ́ kí a mọ Olúwa;ẹ jẹ́ kí a tẹ̀síwájú láti mọ̀ ọ́n.Gẹ́gẹ́ bí oòrùn ṣe ń yọ,yóò jáde;yóò tọ̀ wá wá bí òjò,bí òjò àkọ́rọ̀ ti ń bomirin ilẹ̀.”
4“Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Efraimu?Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Juda?Ìfẹ́ rẹ dàbí ìkùùkuu òwúrọ̀bí ìrì ìdájí tí ó kọjá lọ kíákíá.5Nítorí náà ni mo ṣe gé e yín sí wẹ́wẹ́ láti ọwọ́ àwọn wòlíì,Mo pa yín pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹnu mi,ìdájọ́ mi tàn bí i mọ̀nàmọ́ná lórí yín.6Nítorí àánú ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ;àti ìmọ̀ Ọlọ́run ju ọrẹ ẹbọ sísun lọ.7Bí i Adamu, wọ́n da májẹ̀múwọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí mi níbẹ̀.8Gileadi jẹ́ ìlú àwọn ènìyàn búburútí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, a sí ti fi ẹ̀ṣẹ̀ bà á jẹ́.9Bí adigunjalè ṣe ń ba ní bùba de àwọn ènìyànbẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà, ń parapọ̀;tí wọ́n sì ń pànìyàn lójú ọ̀nà tó lọ sí Ṣekemu,tí wọ́n sì ń dá ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ni lójú.10Mo ti rí ohun tó ba ni lẹ́rùní ilé Israẹli.Níbẹ̀ Efraimu, fi ara rẹ̀ fún àgbèrèIsraẹli sì di aláìmọ́.
11“Àti fún ìwọ, Juda,a ti yan ọjọ́ ìkórè rẹ.“Nígbà tí mo bá fẹ́ dá ohun ìní àwọn ènìyàn mi padà,