1“Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yìn àlùfáà!Ẹ fetísílẹ̀ ẹ̀yin ọmọ Israẹli!Ẹ gbọ́, ẹ̀yìn ilé ọba!Ìdájọ́ yìí kàn yín.Ẹ ti jẹ́ ẹ̀bìtì ní Mispaàwọ̀n ti a nà sílẹ̀ lórí Tabori.2Àwọn ọlọ̀tẹ̀ ti gbilẹ̀ nínú ìpànìyàngbogbo wọn ni èmi ó bá wí,3mo mọ ohun gbogbo nípa EfraimuIsraẹli kò sì pamọ́ fún miEfraimu, ní báyìí ó ti ṣe àgbèrèIsraẹli sì ti díbàjẹ́.4“Ìṣe wọn kò gbà wọ́n láààyèláti padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọn.Ẹ̀mí àgbèrè wà ni ọkàn wọn,wọn kò sì mọ Olúwa.5Ìgbéraga Israẹli ń jẹ́rìí lé wọn;àwọn ọmọ Israẹli, àti Efraimu pàápàá kọsẹ̀ nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.Juda náà sì kọsẹ̀ pẹ̀lú wọn.6Nígbà tí wọ́n bá lọ pẹ̀lú agbo ẹranàti ọ̀wọ́ ẹran wọn láti wá Olúwa,wọn kò ní rí i,ó ti yọ ara rẹ̀ kúrò láàrín wọn.7Wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Olúwawọ́n sì bí àwọn àjèjì ọmọ.Nísinsin yìí, ọdún oṣù tuntun wọn,ni yóò pa wọn run pẹ̀lú ìpín wọn.8“Fọn fèrè ní Gibeah,kí ẹ sì fun ìpè ní Rama.Ẹ pariwo ogun ní Beti-Afeni;máa wárìrì, ìwọ Benjamini.9Efraimu yóò di ahoroní ọjọ́ ìbáwíláàrín àwọn ẹ̀yà Israẹli,Mo sọ ohun tí ó dájú.10Àwọn olórí Juda dàbí àwọn tí ímáa yí òkúta ààlà kúrò.Èmi ó tú ìbínú gbígbóná mi léwọn lórí bí ìkún omi.11A ni Efraimu lára,a sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ ní ìdájọ́,nítorí pé, ó pinnu láti tẹ̀lé òrìṣà.12Mo dàbí kòkòrò aṣọ sí Efraimu,Mo sì dàbí ìdin ara Juda.13“Nígbà ti Efraimu ri àìsàn rẹ̀,tí Juda sì rí ojú egbò rẹ̀ni Efraimu bá tọ ará Asiria lọ,ó sì ránṣẹ́ sí ọba ńlá náà fún ìrànlọ́wọ́.Ṣùgbọ́n kò le è wò ó sànbẹ́ẹ̀ ni kò le wo ojú egbò rẹ̀ jinná.14Nítorí pé, èmi ó dàbí kìnnìún sí Efraimu,bí i kìnnìún ńlá sí ilé Juda.Èmi ó fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ èmi ó sì lọ;Èmi ó gbé wọn lọ, láìsí ẹni tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀.15Nígbà náà ni èmi ó padà lọ sí ààyè mitítí di ìgbà tí wọn ó fi gbà pé àwọn jẹ̀biwọn yóò sì wá ojú minínú ìpọ́njú wọn, wọn ó fi ìtara wá mi.”