Gẹnẹsisi37yor_bib
Àlá Josẹfu
1Jakọbu sì gbé ilẹ̀ Kenaani ní ibi ti baba rẹ̀ ti gbé.2Èyí ni àwọn ìtàn Jakọbu.Nígbà tí Josẹfu di ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún, ó ń ṣọ́ agbo ẹran pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn ọmọ Biliha àti Silipa aya baba rẹ̀ Josẹfu sì ń ròyìn àwọn aburú tí wọ́n ń ṣe fún baba wọn.3Israẹli sì fẹ́ràn Josẹfu ju gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ tókù lọ, nítorí ní ọjọ́ ogbó rẹ̀ ni ó bí i. O sì dá aṣọ aláràbarà tí ó kún fún onírúurú ọnà lára fún un.4Nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ rí i pé baba àwọn fẹ́ràn rẹ̀ ju gbogbo wọn lọ, wọ́n kórìíra rẹ̀, wọ́n sì ń fi ẹ̀tanú bá a gbé, kò sì sí àlàáfíà láàrín wọn.5Josẹfu lá àlá kan, nígbà tí ó sì sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀, wọ́n túbọ̀ kórìíra rẹ̀ sí i.6O wí fún wọn pé, “Ẹ fetí sí àlá tí mo lá,7sá à wò ó, àwa ń yí ìtí ọkà nínú oko, ó sì ṣe ìtí ọkà tèmi sì dìde dúró ṣánṣán, àwọn ìtí ọkà tiyín sì dúró yí ìtí tèmi ká, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún un.”8Àwọn arákùnrin rẹ̀ wí fún un pé, “Ìwọ ń gbèrò àti jẹ ọba lé wa lórí bí? Tàbí ìwọ ó ṣe olórí wa nítòótọ́?” Wọn sì túbọ̀ kórìíra rẹ̀ sí i, nítorí àlá rẹ̀ àti nítorí ohun tí ó wí.9O sì tún lá àlá mìíràn, ó sì tún sọ ọ́ fún àwọn arákùnrin rẹ̀. Ó wí pé, ẹ tẹ́tí sí mi, “Mo tún lá àlá mìíràn, wò ó, oòrùn, òṣùpá àti ìràwọ̀ mọ́kànlá ń foríbalẹ̀ fún mi.”10Nígbà tí ó sọ fún baba rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú, baba rẹ̀ bá a wí pé, “Irú àlá wo ni ìwọ lá yìí? Ṣé ìyá rẹ, pẹ̀lú èmi àti àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ yóò wá foríbalẹ̀ níwájú rẹ ni?”11Àwọn arákùnrin rẹ̀ sì ń ṣe ìlara rẹ̀ ṣùgbọ́n baba rẹ̀ pa ọ̀rọ̀ náà mọ́ lọ́kàn rẹ̀.