Esekiẹli3yor_bib
1Síwájú sí i, ó sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, jẹ ohun tí ó wà níwájú rẹ, jẹ ìwé kíká yìí; kí o sì lọ fi bá ilé Israẹli sọ̀rọ̀.”2Mo sì ya ẹnu mi, ó sì mú mi jẹ ìwé kíká náà.3Ó tún sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, jẹ ìwé kíká tí mo fún ọ yìí, fi bọ́ inú àti ikùn rẹ.” Nígbà náà ni mo jẹ ẹ́, dídùn rẹ̀ dàbí oyin ní ẹnu mi.4Ó sì tún sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, lọ ni ìsinsin yìí bá mi sọ ọ̀rọ̀ mi fún ilé Israẹli.5A kò rán ọ sí àwọn tó ń sọ èdè àjèjì tàbí tí èdè wọn ṣòro láti gbọ́, ṣùgbọ́n orílẹ̀-èdè Israẹli ni mo rán ọ sí6kì í ṣe sí ọ̀pọ̀ ènìyàn tó ń sọ àjèjì èdè tàbí tí èdè wọn ṣòro láti gbọ́, àwọn tí ọ̀rọ̀ wọn le fún ọ láti gbọ́ yé. Dájúdájú bí mo bá rán ọ sí wọn, wọn ìbá sì fetísílẹ̀ sí ọ.7Ṣùgbọ́n ilé Israẹli kò fẹ́ gbọ́ tìrẹ nítorí pé wọn kò fẹ́ láti gbọ́ tèmi, torí pé aláìgbọ́ràn àti ọlọ́kàn líle ni gbogbo ilé Israẹli.8Ṣùgbọ́n bí i tiwọn lèmi náà yóò ṣe jẹ́ kí ojú àti ọkàn rẹ le.9Èmi yóò ṣe iwájú orí rẹ bí òkúta tó le jùlọ, ànító le ju òkúta-ìbọn lọ. Má ṣe bẹ̀rù wọn tàbí jẹ́ kí wọn ó dáyà já ọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.”10Ó sì sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ń sọ, kí o sì gba gbogbo ọ̀rọ̀ yìí sí ọkàn rẹ.11Lọ nísinsin yìí sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ tó wà ní ìgbèkùn. Sọ fún wọn pé báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí yálà wọ́n gbọ́ tàbí wọn kò gbọ́.”12Nígbà náà ni ẹ̀mí gbé mi sókè, mo sì gbọ́ ohùn ìró ńlá lẹ́yìn mi tó sọ pé, kí a gbé ògo Olúwa ga láti ibùgbé rẹ̀ wá!13Bẹ́ẹ̀ ni mo tún gbọ́ ariwo ìyẹ́ apá àti kẹ̀kẹ́ àwọn ẹ̀dá alààyè náà pẹ̀lú ariwo tó dàbí àrá ńlá.14Ẹ̀mí náà sì gbé mi sókè, ó sì mú mi lọ, mo lọ pẹ̀lú ọkàn kíkorò àti ìbínú nínú ẹ̀mí mi, pẹ̀lú ọwọ́ líle Olúwa ni ara mi.15Nígbà náà ni mo lọ sí etí odò Kebari níbi tí àwọn ìgbèkùn ń gbé ni Teli-Abibu. Níbẹ̀ níbi tí wọ́n ń gbé, mo jókòó láàrín wọn pẹ̀lú ìyanu, fún ọjọ́ méje.