1Orúkọ rere sàn ju ìpara olóòórùn dídùn lọ,ọjọ́ ikú sì dára ju ọjọ́ tí a bí ènìyàn lọ.2Ó dára láti lọ sí ilé ọ̀fọ̀ju ibi àsè,nítorí pé ikú jẹ́ àyànmọ́ gbogbo ènìyàn;kí alààyè ní èyí ní ọkàn.3Ìbànújẹ́ dára ju ẹ̀rín lọ,ó le è mú kí ojú rẹ̀ dàrú,ṣùgbọ́n yóò jẹ́ kí àyà rẹ le.4Ọkàn ọlọ́gbọ́n wà ní ilé ọ̀fọ̀,ṣùgbọ́n ọkàn òmùgọ̀ ní ilé àríyá.5Ó dára láti gba ìbáwí ọlọ́gbọ́n,ju fífetísílẹ̀ sí orin òmùgọ̀ lọ.6Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gún ti ń dún lábẹ́ ìkòkòni ẹ̀rín òmùgọ̀.Asán sì ni eléyìí pẹ̀lú.7Ìrẹ́jẹ a máa sọ ọlọ́gbọ́n di òmùgọ̀,àbẹ̀tẹ́lẹ̀ sì máa ń ba ìwà jẹ́ ni.8Òpin ọ̀rọ̀ dára ju ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ lọ,sùúrù sì dára ju ìgbéraga lọ.9Má ṣe yára bínú ní ọkàn rẹnítorí pé orí ẹsẹ̀ òmùgọ̀ ni ìbínú ń gbé.10Má ṣe sọ wí pé, “Kí ni ìdí tí àtijọ́ fi dára ju èyí?”Nítorí pé, kò mú ọgbọ́n wá láti béèrè irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀.11Ọgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ogún ìní jẹ́ ohun tí ó dáraó sì ṣe àwọn tí ó rí oòrùn láǹfààní.12Ọgbọ́n jẹ́ ààbògẹ́gẹ́ bí owó ti jẹ́ ààbòṣùgbọ́n àǹfààní òye ni èyípé ọgbọ́n a máa tọ́jú ẹ̀mí ẹni tí ó bá ní.13Wo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe:“Ta ni ó le è toohun tí ó ti ṣe ní wíwọ́?”14Nígbà tí àkókò bá dára, jẹ́ kí inú rẹ dùn,ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò kò bá dára, rò ó:Ọlọ́run tí ó dá èkínnínáà ni ó dá èkejì.Nítorí náà, ènìyàn kò le è ṣàwáríohun kankan nípa ọjọ́ iwájú rẹ̀.15Nínú ayé àìní ìtumọ̀ yìí ni mo ti rí gbogbo èyíènìyàn olóòtítọ́, ọkùnrin olódodo ń parun nínú òtítọ́ rẹ̀ìkà ènìyàn sì ń gbé ìgbé ayé pípẹ́ nínú ìkà rẹ̀.16Má ṣe jẹ́ olódodo jùlọtàbí ọlọ́gbọ́n jùlọkí ló dé tí o fi fẹ́ pa ara rẹ run?17Ìwọ ma ṣe búburú jùlọ kí ìwọ má sì ṣe aṣiwèrè,èéṣe tí ìwọ yóò fi kú kí ọjọ́ rẹ tó pé18Ó dára láti mú ọ̀kankí o má sì ṣe fi èkejì sílẹ̀.Ọkùnrin tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run yóò bọ́ lọ́wọ́ gbogbo àrékérekè.19Ọgbọ́n máa ń mú kí ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní agbáraju alákòóso mẹ́wàá lọ ní ìlú.20Kò sí olódodo ènìyàn kan láyétí ó ṣe ohun tí ó tọ́ tí kò dẹ́ṣẹ̀ rárá.21Má ṣe kíyèsi gbogbo ọ̀rọ̀ tí ènìyàn ń sọbí bẹ́ẹ̀ kọ́, o le è gbọ́ pé ìránṣẹ́ rẹ ń ṣépè fún ọ.22Tí o sì mọ̀ nínú ọkàn rẹpé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìwọ fúnra rẹ̀ ti ṣépè fún àwọn ẹlòmíràn.23Gbogbo èyí ni mo ti dánwò nípa ọgbọ́n, tí mo sì wí pé,“Mo pinnu láti jẹ́ ọlọ́gbọ́n”;ṣùgbọ́n eléyìí ti jù mí lọ.24Ohun tí ó wù kí ọgbọ́n le è jẹ́,ó ti lọ jìnnà, ó sì jinlẹ̀ta ni ó le è ṣe àwárí rẹ̀?25Mo wá rò ó nínú ọkàn mi láti mọ̀,láti wá àti láti ṣàwárí ọgbọ́nàti ìdí ohun gbogbo, àti láti mọ ìwà àgọ́búburú àti ti ìsínwín tàbí òmùgọ̀.26Mo rí ohun tí ó korò ju ikú lọobìnrin tí ó jẹ́ ẹ̀bìtì,tí ọkàn rẹ̀ jẹ́ tàkútétí ọwọ́ rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀wọ̀n,ọkùnrin tí ó bá tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn yóò le è yọ sílẹ̀ṣùgbọ́n ẹni dẹ́ṣẹ̀ kò le è bọ́ nínú tàkúté rẹ̀.27Oniwaasu wí pé, “Wò ó, eléyìí ni ohun tí mo ti ṣàwárí:“Mímú ohun kan pọ̀ mọ́ òmíràn láti ṣàwárí ìdí ohun gbogbo.28Nígbà tí mo sì ń wá a kiriṣùgbọ́n tí n kò rí imo rí ọkùnrin tí ó dúró dáradára kan láàrín ẹgbẹ̀rún (1,000),ṣùgbọ́n n kò rí obìnrin,kankan kí ó dúró láàrín gbogbo wọn.29Eléyìí nìkan ni mo tí ì rí:Ọlọ́run dá ìran ènìyàn dáradára,ṣùgbọ́n ènìyàn ti lọ láti ṣàwárí ohun púpọ̀.”