Oniwaasu12yor_bib
1Rántí Ẹlẹ́dàá rẹní ọjọ́ èwe rẹ,nígbà tí ọjọ́ ibi kò tí ì déàti tí ọdún kò tí ì ní súnmọ́ etílé, nígbà tí ìwọ yóò wí pé,“Èmi kò ní ìdùnnú nínú wọn,”2kí oòrùn àti ìmọ́lẹ̀àti òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tó ṣókùnkùn,àti kí àwọsánmọ̀ tó padà lẹ́yìn òjò;3nígbà tí olùṣọ́ ilé yóò wárìrìtí àwọn ọkùnrin alágbára yóò tẹríba,nígbà tí àwọn tí ó ń lọ dákẹ́ nítorí pé wọn kò pọ̀,tí àwọn tí ń wo òde láti ojú fèrèsé yóò ṣókùnkùn;4nígbà tí ìlẹ̀kùn sí ìgboro yóò tìtí ariwo ọlọ yóò dákẹ́;nígbà tí àwọn ènìyàn yóò dìde sí ariwo àwọn ẹyẹṣùgbọ́n gbogbo orin wọn yóò máa lọ ilẹ̀.5Nígbà tí ènìyàn yóò bẹ̀rù ibi gígaàti ti ìfarapa ní ìgboro;nígbà tí igi almondi yóò tannáàti tí ẹlẹ́ǹgà yóò wọ́ ara rẹ̀ lọtí ìfẹ́ kò sì ní ru sókè mọ́nígbà náà ni ènìyàn yóò lọ ilé rẹ́ ayérayétí àwọn aṣọ̀fọ̀ yóò máa rìn kiri ìgboro.6Rántí rẹ̀ kí okùn fàdákà tó já,tàbí kí ọpọ́n wúrà tó fọ́;kí iṣà tó fọ́ níbi ìsun,tàbí kí àyíká kẹ̀kẹ́ kí ó tó kán níbi kànga.7Tí erùpẹ̀ yóò sì padà sí ilẹ̀ ibi tí ó ti wà,tí ẹ̀mí yóò sì padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run tí ó fi í fún ni.8“Asán! Asán!” ni Oniwaasu wí.“Gbogbo rẹ̀ asán ni!”