Oniwaasu11yor_bib

Àkàrà lórí omi

1Fún àkàrà rẹ sórí omi,nítorí lẹ́yìn ọjọ́ púpọ̀, ìwọ yóò rí i padà.2Fi ìpín fún méje, àní fún mẹ́jọ pẹ̀lú,nítorí ìwọ kò mọ ohun ìparun tí ó le è wá sórí ilẹ̀.
3Bí àwọsánmọ̀ bá kún fún omi,ayé ni wọ́n ń rọ òjò sí.Bí igi wó sí ìhà gúúsù tàbí sí ìhà àríwá,níbi tí ó wó sí náà, ni yóò dùbúlẹ̀ sí.4Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wo afẹ́fẹ́ kò ní fúnrúgbìn;ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wo àwọsánmọ̀ kò ní kórè.
5Gẹ́gẹ́ bí ìwọ kò ti ṣe mọ ojú ọ̀nà afẹ́fẹ́tàbí mọ bí ọmọ tí ń dàgbà nínú ikùn ìyáarẹ̀,bẹ́ẹ̀ náà ni ìwọ kò le è ní òye iṣẹ́ Ọlọ́runẹlẹ́dàá ohun gbogbo.
6Fún irúgbìn rẹ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù,má sì ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ ṣọlẹ̀ ní àṣálẹ́,nítorí ìwọ kò mọ èyí tí yóò ṣe rerebóyá èyí tàbí ìyẹntàbí àwọn méjèèjì ni yóò ṣe dáradára bákan náà.

Rántí ẹlẹ́dàá rẹ ní ìgbà èwe rẹ

7Ìmọ́lẹ̀ dùn;Ó sì dára fún ojú láti rí oòrùn.8Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ènìyàn jẹ̀gbádùn gbogbo iye ọdúntí ó le è lò láyéṣùgbọ́n jẹ́ kí ó rántí ọjọ́ òkùnkùnnítorí wọn ó pọ̀.Gbogbo ohun tí ó ń bọ̀ asán ni.
9Jẹ́ kí inú rẹ dùn, ìwọ ọ̀dọ́mọdé ní ìgbà tí o wà ní èwekí o sì jẹ́ kí ọkàn rẹ fún ọ ní ayọ̀ ní ìgbà èwe rẹ.Tẹ̀lé ọ̀nà ọkàn rẹàti ohunkóhun tí ojú rẹ ríṣùgbọ́n mọ̀ dájú pé nípa gbogbo nǹkan wọ̀nyí niỌlọ́run yóò mú ọ wá sí ìdájọ́.10Nítorí náà, mú ìjayà kúrò ní ọkàn rẹkí o sì lé ìbànújẹ́ ara rẹ kúrònítorí èwe àti kékeré kò ní ìtumọ̀.