Oniwaasu10yor_bib
1Gẹ́gẹ́ bí òkú eṣinṣin tí ń fún òróró ìkunra ní òórùn búburú,bẹ́ẹ̀ náà ni òmùgọ̀ díẹ̀ ṣe ń bo ọgbọ́n àti ọlá mọ́lẹ̀.2Ọkàn ọlọ́gbọ́n a máa ṣí sí ohun tí ó tọ̀nà,ṣùgbọ́n ọkàn òmùgọ̀ sí ohun tí kò dára.3Kódà bí ó ti ṣe ń rìn láàrín ọ̀nà,òmùgọ̀ kò ní ọgbọ́na sì máa fihan gbogbo ènìyàn bí ó ti gọ̀ tó.4Bí ìbínú alákòóso bá dìde lòdì sí ọ,ma ṣe fi ààyè rẹ sílẹ̀;ìdákẹ́ jẹ́ẹ́jẹ́ le è tú àṣìṣe ńlá.5Ohun ibi kan wà tí mo ti rí lábẹ́ oòrùn,irú àṣìṣe tí ó dìde láti ọ̀dọ̀ alákòóso.6A gbé aṣiwèrè sí ọ̀pọ̀ ipò tí ó ga jùlọ,nígbà tí ọlọ́rọ̀ gba àwọn ààyè tí ó kéré jùlọ.7Mo ti rí ẹrú lórí ẹṣin,nígbà tí ọmọ-aládé ń fi ẹsẹ̀ rìn bí ẹrú.8Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́ kòtò, ó le è ṣubú sínú rẹ̀;ẹnikẹ́ni tí ó bá la inú ògiri, ejò le è ṣán an.9Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbe òkúta le è ní ìpalára láti ipasẹ̀ wọn;ẹnikẹ́ni tí ó bá la ìtì igi le è ní ìpalára láti ipasẹ̀ wọn.10Bí àáké bá kútí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kò sì sí ní pípọ́n;yóò nílò agbára púpọ̀ṣùgbọ́n ọgbọ́n orí ni yóò mú àṣeyọrí wá.11Bí ejò bá ṣán ni kí a tó lo oògùn rẹ̀,kò sí èrè kankan fún olóògùn rẹ̀.12Ọ̀rọ̀ tí ó wá láti ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa ní oore-ọ̀fẹ́ṣùgbọ́n ètè òmùgọ̀ fúnra rẹ̀ ni yóò parun.13Ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ òmùgọ̀;ìparí rẹ̀ sì jẹ́ ìsínwín búburú.14Wèrè a sì máa ṣàfikún ọ̀rọ̀.Kò sí ẹni tí ó mọ ohun tí ó ń bọ̀ta ni ó le è sọ fún un ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀?15Iṣẹ́ aṣiwèrè a máa dá a lágarakò sì mọ ojú ọ̀nà sí ìlú.16Ègbé ni fún ọ, ìwọ ilẹ̀ tí ọba ń ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀àti tí àwọn ọmọ-aládé ń ṣe àsè ní òwúrọ̀.17Ìbùkún ni fún ọ, ìwọ ilẹ̀ èyí tí ọba rẹ̀ jẹ́ ọmọ ọlọ́lá,àti tí àwọn ọmọ-aládé ń jẹun ní àsìkò tí ó yẹ,fún ìlera, tí kì í ṣe fún ìmutípara.18Bí ènìyàn bá ń lọ́ra, àjà ilé a máa jìbí ọwọ́ rẹ̀ bá ń ṣe ọ̀lẹ, ilé a máa jó.19Ẹ̀rín rínrín ni a ṣe àsè fún,wáìnì a máa mú ayé dùn,ṣùgbọ́n owó ni ìdáhùn sí ohun gbogbo.20Ma ṣe bú ọba, kódà nínú èrò rẹ,tàbí kí o ṣépè fún ọlọ́rọ̀ ní ibi ibùsùn rẹ,nítorí pé ẹyẹ ojú ọ̀run le è gbé ọ̀rọ̀ rẹẹyẹ tí ó sì ní ìyẹ́ apá le è fi ẹjọ́ ohun tí o sọ sùn.