Deuteronomi32yor_bib
1Fetísílẹ̀, ẹ̀yin ọ̀run, èmi yóò sọ̀rọ̀;ẹ gbọ́, ìwọ ayé, ọ̀rọ̀ ẹnu mi.2Jẹ́ kí ẹ̀kọ́ ọ̀ mi máa rọ̀ bí òjò,kí àwọn ọ̀rọ̀ mi máa sọ̀kalẹ̀ bí ìrì,bí òjò wíníwíní sára ewéko tuntun,bí ọ̀wààrà òjò sára ohun ọ̀gbìn.3Èmi yóò kókìkí orúkọ Olúwa.Ẹyin títóbi Ọlọ́run wa!4Òun ni àpáta, iṣẹ́ ẹ rẹ̀ jẹ́ pípé,gbogbo ọ̀nà an rẹ̀ jẹ́ òdodo.Ọlọ́run olóòtítọ́ tí kò ṣe àṣìṣe kan,Ó dúró ṣinṣin, òdodo àti òtítọ́ ni òun.5Wọ́n ti ṣe iṣẹ́ ìbàjẹ́ sọ́dọ̀ ọ rẹ̀;fún ìtìjú u wọn, wọn kì í ṣe ọmọ rẹ̀ mọ́,ṣùgbọ́n ìran tí ó yí sí apá kan tí ó sì dorí kodò.6Ṣé báyìí ni ẹ̀yin yóò ṣe san an fún Olúwa,ẹ̀yin aṣiwèrè àti aláìgbọ́n ènìyàn?Ǹjẹ́ òun kọ́ ni baba yín, Ẹlẹ́dàá yín,tí ó dá a yín tí ó sì mọ yín?7Rántí ìgbà láéláé;wádìí àwọn ìran tí ó ti kọjá.Béèrè lọ́wọ́ baba à rẹ yóò sì sọ fún ọ,àwọn àgbàgbà rẹ, wọn yóò sì ṣàlàyé fún ọ.8Nígbà tí Ọ̀gá-ògo fi ogún àwọn orílẹ̀-èdè fún wọn,nígbà tí ó pín onírúurú ènìyàn,ó sì gbé ààlà kalẹ̀ fún àwọn ènìyàngẹ́gẹ́ bí iye ọmọkùnrin Israẹli.9Nítorí ìpín Olúwa ni àwọn ènìyàn an rẹ̀,Jakọbu ni ìpín ìní i rẹ̀.10Ní aginjù ni ó ti rí i,ní aginjù níbi tí ẹranko kò sí.Ó yíká, ó sì tọ́jú rẹ̀,ó pa á mọ́ bí ẹyin ojú u rẹ̀.11Bí idì ti í ru ìtẹ́ rẹ̀ ti ó sì ńrábàbà sórí ọmọ rẹ̀,tí ó na ìyẹ́ apá rẹ̀ láti gbé wọn ki ó sìgbé wọn sórí ìyẹ́ apá rẹ̀.12Olúwa ṣamọ̀nà;kò sì sí ọlọ́run àjèjì pẹ̀lú rẹ̀.13Ó mú gun ibi gíga ayéó sì fi èso oko bọ́ ọ.Ó sì jẹ́ kí ó mú oyin láti inú àpáta wá,àti òróró láti inú akọ òkúta wá.14Pẹ̀lú u wàràǹkàṣì àti wàrà àgùntànàti ti àgbò ẹranàti pẹ̀lú ọ̀rá ọ̀dọ́-àgùntàn àti ewúrẹ́,pẹ̀lú àgbò irú u ti Baṣanití ó sì mu ẹ̀jẹ̀ èso àjàrà, àní àti wáìnì.15Jeṣuruni sanra tán ó sì tàpá;ìwọ sanra tán, ìwọ ki tan, ọ̀rá sì bò ọ́ tán.O kọ Ọlọ́run tí ó dá ọo sì kọ àpáta ìgbàlà rẹ.16Wọ́n sì fi òrìṣà mú un jowú,ohun ìríra ni wọ́n fi mú un bínú.17Wọ́n rú ẹbọ sí iwin búburú, tí kì í ṣe Ọlọ́run,ọlọ́run tí wọn kò mọ̀ rí,ọlọ́run tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ farahàn láìpẹ́,ọlọ́run tí àwọn baba yín kò bẹ̀rù.18Ìwọ kò rántí àpáta, tí ó bí ọ;o sì gbàgbé Ọlọ́run tí ó dá ọ.19Olúwa sì rí èyí ó sì kọ̀ wọ́n,nítorí tí ó ti bínú nítorí ìwà ìmúnibínú àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ.20Ó sì wí pé, “Èmi yóò pa ojú mi mọ́ kúrò lára wọn,èmi yóò sì wò ó bí ìgbẹ̀yìn in wọn yóò ti rí;nítorí wọ́n jẹ́ ìran alágídí,àwọn ọmọ tí kò sí ìgbàgbọ́ nínú wọn.21Wọ́n fi mí jowú nípa ohun tí kì í ṣe Ọlọ́run,wọ́n sì fi ohun asán an wọn mú mi bínú.Èmi yóò mú wọn kún fún ìlara láti ọ̀dọ̀ àwọn tí kì í ṣe ènìyàn;èmi yóò sì mú wọn bínú láti ọ̀dọ̀ aṣiwèrè orílẹ̀-èdè.22Nítorí pé iná kan ràn nínú ìbínú mi,yóò sì jó dé ipò ikú ní ìsàlẹ̀.Yóò sì run ayé àti ìkórè e rẹ̀yóò sì tiná bọ ìpìlẹ̀ àwọn òkè ńlá.23“Èmi yóò kó àwọn ohun búburú lé wọn lóríèmi ó sì na ọfà mi tán sí wọn lára.24Èmi yóò mú wọn gbẹ,ooru gbígbóná àti ìparun kíkorò ni a ó fi run wọ́n.Pẹ̀lú oró ohun tí ń rákò nínú erùpẹ̀.25Idà ní òde, àti ẹ̀rù nínú ìyẹ̀wù,ni yóò run ọmọkùnrin àti wúńdíá.Ọmọ ẹnu ọmú àti arúgbó eléwú irun pẹ̀lú.26Mo ní èmi yóò tú wọn káèmi yóò sì mú ìrántí i wọn dà kúrò nínú àwọn ènìyàn,27nítorí bí mo ti bẹ̀rù ìbínú ọ̀tá,kí àwọn ọ̀tá a wọn kí ó mába à wí pé, ‘Ọwọ́ wa lékè ni;kì í sì í ṣe Olúwa ni ó ṣe gbogbo èyí.’ ”28Wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè tí kò ní ìmọ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò sí òye nínú wọn.29Bí ó ṣe pé wọ́n gbọ́n, kí òye yìí sì yé wọnkí wọn ro bí ìgbẹ̀yìn wọn yóò ti rí!30Báwo ni ẹnìkan ṣe lè lé ẹgbẹ̀rún (1,000),tàbí tí ẹni méjì sì lè lé ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) sá,bí kò ṣe pé àpáta wọn ti tà wọ́n,bí kò ṣe pé Olúwa wọn ti fi wọ́n tọrẹ?31Nítorí pé àpáta wọn kò dàbí àpáta wa,àní àwọn ọ̀tá wa tìkára wọn ń ṣe onídàájọ́.32Igi àjàrà a wọn wá láti igi àjàrà Sodomuàti ti ìgbẹ́ ẹ Gomorra.Èso àjàrà wọn kún fún oró,ìdì wọn korò.33Ọtí wáìnì wọn ìwọ ti dragoni ni,àti oró mímú ti ejò paramọ́lẹ̀.34“Èmi kò to èyí jọ ní ìpamọ́èmi kò sì fi èdìdì dì í ní ìṣúra mi?35Ti èmi ni láti gbẹ̀san. Èmi yóò san án fún wọnní àkókò tí ẹ̀ṣẹ̀ wọn yóò yọ;ọjọ́ ìdààmú wọn súnmọ́ etíléohun tí ó sì ń bọ̀ wá bá wọn yára bọ̀.”36Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn an rẹ̀yóò sì ṣàánú fún àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀nígbà tí ó bá rí i pé agbára wọn lọ tántí kò sì sí ẹnìkan tí ó kù, ẹrú tàbí ọmọ.37Yóò wí pé, “Òrìṣà wọn dà báyìí,àpáta tí wọ́n fi ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé e wọn,38ọlọ́run tí ó jẹ ọ̀rá ẹran ẹbọ wọntí ó ti mu ọtí i wáìnì ẹbọ ohun mímu wọn?Jẹ́ kí wọn dìde láti gbà wọ́n!Jẹ́ kí wọn ṣe ààbò fún un yín!39“Wò ó báyìí pé, Èmi fúnra à mi, Èmi ni!Kò sí ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn mi.Mo sọ di kíkú mo sì tún sọ di ààyè.Mo ti ṣá lọ́gbẹ́ Èmi yóò sì mu jiná,kò sí ẹni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ ọ̀ mi.40Mo gbé ọwọ́ mi sókè ọ̀run mo sì wí pé,Èmi ti wà láààyè títí láé,41nígbà tí mo bá pọ́n idà dídán miàti tí mo bá sì fi ọwọ́ mi lé ìdájọ́,Èmi yóò san ẹ̀san fún àwọn ọ̀tá miÈmi ó sì san fún àwọn tí ó kórìíra à mi.42Èmi yóò mú ọfà mu ẹ̀jẹ̀,nígbà tí idà mi bá jẹ ẹran:ẹ̀jẹ̀ ẹni pípa àti ẹni ìgbèkùn,láti orí àwọn aṣáájú ọ̀tá.”43Ẹ yọ̀ ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀nítorí òun yóò gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀;yóò sì gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá a rẹ̀yóò sì ṣe ètùtù fún ilẹ̀ àti ènìyàn rẹ̀.44Mose sì wá ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí ní etí àwọn ènìyàn náà, òun, àti Hosea ọmọ Nuni.45Nígbà tí Mose parí i kíka gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí Israẹli.46Ó sọ fún un pé, “Ẹ gbé ọkàn an yín lé gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ láàrín yín lónìí, kí ẹ̀yin lè pàṣẹ fún àwọn ọmọ yín láti gbọ́rọ̀ àti láti ṣe gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin yìí.47Wọn kì í ṣe ọ̀rọ̀ asán fún ọ, ìyè e yín ni wọ́n. Nípa wọn ni ẹ̀yin yóò gbé pẹ́ lórí ilẹ̀ tí ẹ̀yin ń gòkè e Jordani lọ láti gbà.”