Amosi2yor_bib

1Èyí ni ohun tí Olúwa wí,“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Moabu,àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà,nítorí ó ti sun ún, di eérú,egungun ọba Edomu,2Èmi yóò rán iná sí orí Moabuèyí tí yóò jó àwọn ààfin Kerioti run.Moabu yóò sì kú pẹ̀lú ariwopẹ̀lú igbe àti pẹ̀lú ìró ìpè.3Èmi yóò ké onídàájọ́ rẹ̀ kúrò,Èmi yóò sì pa gbogbo àwọn ọmọ-aládé rẹ́ nínú rẹ̀,”ni Olúwa wí.4Èyí ni ohun tí Olúwa wí,“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Juda,àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà.Nítorí wọn ti kọ òfin Olúwa sílẹ̀,wọn kò sì pa àwọn ìlànà rẹ̀ mọ́.Nítorí àwọn òrìṣà ti sì wọ́n lọ́nà,òrìṣà tí àwọn Baba ńlá wọn ń tẹ̀lé,5Èmi yóò rán iná sí orí Judaèyí tí yóò jó àwọn ààfin Jerusalẹmu run.”

Ìdájọ́ tí yóò wá sórí Israẹli

6Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta Israẹliàní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà.Wọ́n ta olódodo fún fàdákààti aláìní fún bàtà ẹsẹ̀ méjèèjì.7Wọ́n fi ẹsẹ̀ tẹ orí àwọn tálákà mọ́lẹ̀,bí wọ́n ti ń tẹ erùpẹ̀ ilẹ̀tí wọ́n ko sì ṣe òtítọ́ si àwọn tí a ni lára.Baba àti ọmọ ń wọlé tọ wúńdíá kan náà,láti ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́.8Wọ́n dùbúlẹ̀ lẹ́bàá a pẹpẹ,lórí aṣọ tí wọ́n fi jẹ́ ẹ̀jẹ́ní ilé òrìṣà wọnwọ́n sì mu ọtí tí wọ́n san fún ìtánràn.
9“Mo pa àwọn ará Amori run níwájú wọngíga ẹni tí ó dàbí igi kedari.Òun sì le koko bí igi óákùmo pa èso rẹ̀ run láti òkè wáàti egbò rẹ̀ láti ìsàlẹ̀ wá.10Èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá,mo sì sìn yín la aginjù já ní ogójì ọdúnláti fi ilẹ̀ àwọn ará Amori fún un yín.
11“Èmi sì tún gbé àwọn wòlíì dìde láàrín àwọn ọmọ yínàti láàrín àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín láti jẹ Nasirièyí kò ha jẹ́ òtítọ́ bí ará Israẹli?”ni Olúwa wí.12“Ṣùgbọ́n ẹ̀yin fún àwọn Nasiri ní ọtí mue sì pàṣẹ fún àwọn wòlíì kí wọ́n má ṣe sọtẹ́lẹ̀.
13“Ní báyìí, èmi yóò tẹ̀ yín mọ́lẹ̀bí kẹ̀kẹ́ tí ó kún fún ìtí ti í tẹ̀.14Ẹni tí ó yára bí àṣá kò ní rí ọ̀nà àbáyọalágbára kò ní le è dúró lé agbára rẹ̀jagunjagun kì yóò le gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là.15Tafàtafà kì yóò dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó gún ẹṣinkì yóò gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là.16Àní jagunjagun tí ó gbóyà jùlọyóò sálọ ní ìhòhò ní ọjọ́ náà,”ni Olúwa wí.