Amosi1yor_bib
1Àwọn ọ̀rọ̀ Amosi, ọ̀kan lára àwọn olùṣọ́-àgùntàn Tekoa; ohun tí o rí nípa Israẹli ní ọdún méjì ṣáájú ilẹ̀-rírì, nígbà tí Ussiah ọba Juda àti Jeroboamu ọmọ Jehoaṣi jẹ́ ọba ní ilẹ̀ Israẹli.2Ó wí pé,“Olúwa yóò bú jáde láti Sioni,ohùn rẹ̀ yóò sì sán bí àrá láti Jerusalẹmu wá;ibùgbé àwọn olùṣọ́-àgùntàn yóò sì ṣọ̀fọ̀,orí òkè Karmeli yóò sì rọ.”