1 Kronika3yor_bib
Àwọn ọmọ Dafidi
1Àwọn wọ̀nyí sì ni ọmọ Dafidi tí a bí fún un ní Hebroni.Àkọ́bí sì ni Amnoni ọmọ Ahinoamu ti Jesreeli; èkejì sì ni Daniẹli ọmọ Abigaili ará Karmeli;2ẹ̀kẹta sì ni Absalomu ọmọ Maaka ọmọbìnrin Talmai ọba Geṣuri bí fún un; ẹ̀kẹrin sì ni Adonijah ọmọ Haggiti;3ẹ̀karùnún ni Ṣefatia láti ọ̀dọ̀ Abitali; àti ẹ̀kẹfà, Itreamu, láti ọ̀dọ̀ Egla aya rẹ̀.4Àwọn mẹ́fà wọ̀nyí ni a bí fún Dafidi ni Hebroni, níbi tí ó ti jẹ ọba fún ọdún méje àti oṣù mẹ́fà.
Dafidi sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n.5Wọ̀nyí ni ọmọ wẹ́wẹ́ tí a bí fún un ní Jerusalẹmu:
Ṣimea, Ṣobabu, Natani àti Solomoni. Àwọn mẹ́rin wọ̀nyí sì ni a bí láti ọ̀dọ̀ Bati-Ṣua ọmọbìnrin Ammieli.6Ibhari sì wà pẹ̀lú, Eliṣama, Elifeleti,7Noga, Nefegi, Jafia,8Eliṣama, Eliada àti Elifeleti mẹ́sàn-án ni wọ́n.9Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Dafidi yàtọ̀ sí àwọn ọmọ tí àlè bí fún un. Tamari sì ni arábìnrin wọn.